Pernilla August
Pernilla August | |
---|---|
Pernilla August ní ibi Guldbagge Award ti ọdún 2013 | |
Ọjọ́ìbí | Mia Pernilla Hertzman-Ericson 13 Oṣù Kejì 1958 Stockholm, Sweden |
Orúkọ míràn | Pernilla Östergren |
Iṣẹ́ | Actress, film director |
Ìgbà iṣẹ́ | 1975–present |
Olólùfẹ́ |
|
Àwọn ọmọ | 3, including Alba |
Àwọn olùbátan | Anders August (former stepson) |
Pernilla August (Àdàkọ:IPA-sv; orúkọ tí àwọn òbí rẹ̀ fun ni Mia Pernilla Hertzman-Ericson; tí a bí ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì ọdun 1958)[1] jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orilẹ̀-èdè Sweden. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òṣèrébìnrin tí ó gbajúmọ̀ jùlọ ní Sweden, ó sì ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ pẹ̀lú Ingmar Bergman, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Best Actress ní ayẹyẹ Cannes Film ti ọdún 1992 fún ipa rẹ̀ nínú The Best Intentions. Ó gbajúmọ̀ káàkiri àgbáyé fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Shmi Skywalker nínú eré Star Wars: Episode I – The Phantom Menace àti Star Wars: Episode II – Attack of the Clones.
Àwọn àmì ẹyẹ tí ó ti gbà
Díè nínú àwọn àmì ẹyẹ tí Pernilla ti gbà ni Best Actress ní ayẹyẹ Cannes Film ní ọdún 1992, fún ipa rẹ̀ nínú eré Bille August tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ The Best Intentions.[2] Fún eré kan náà, ó gba àmì-ẹ̀yẹ Best Actress ní 28th Guldbagge Awards.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
- ↑ "Pernilla August". sfi.se. Retrieved 2 January 2017.
- ↑ "Festival de Cannes: The Best Intentions". festival-cannes.com. Retrieved 14 August 2009.
- ↑ "Den goda viljan (1992)". Swedish Film Institute. 22 March 2014.