Àjẹsára Bacillus Calmette–Guérin
Àjẹsára Bacillus Calmette–Guérin (BCG) jẹ́ àjẹsára tí à ń lò ní pàtàkì láti gbógun ti ikọ́-ẹ̀gbẹ.[1] Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ikọ́-ẹ̀gbẹ ti wọ́pọ̀, a gba ni nímọ̀ràn láti lo ìwọ̀n egbògi tí a dá láàbá kanṣoṣo fún àwọn ọmọ-ọwọ́ tí ìlera wọn péye lọ́gán tí a bá ti bí wọn tán.[1] A kò gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ-ọwọ́ tó ní àrún kògbóògùn HIV/AIDS ní àjẹsára.[2] Ní àwọn agbègbè tí ikọ́-ẹ̀gbẹ kò ti wọ́pọ̀, àwọn ọmọ-ọwọ́ tó wà lábẹ́ ewu kíkó àrùn náà níkan ni a má a ń sábà fún ní àjẹsára, a ó sì ṣe ìdánwò láti mọ̀ bóyá àwọn tí a lérò pé wọ́n ní àrùn náà ní i nítòótọ́, a ó sì ṣe ìwòsàn wọn. Àwọn àgbàlagbà tí kò ní ikọ́-ẹ̀gbẹ, tí a kò sì tíì fún ní àjẹsára tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n tí wọ́n má a ń sábà ní oríṣi ikọ́-ẹ̀gbẹ tí kìí tètè gbóògùn ni a lè fún ní àjẹsára pẹ̀lú.[1]
Òṣùwọ̀n agbára àjẹsára náà láti dáàbò bo ni lọ́wọ́ àrùn náà a má a yàtọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, agbára iṣẹ́ rẹ̀ a sì má a wà lára ẹni fún iye àkókò tí ó tó ọdún mẹ́ẹ̀wá sí ogún ọdún.[1] Láàárín àwọn ọmọ-ọwọ́, a má a dènà àkóràn àrùn náà lára iye ìwọ̀n tó tó oogún nínú ọgọ́ọ̀rún àwọn ọmọ-ọwọ́ náà, a sì tún má a dáàbò bo ìdajì lára iye àwọn ọmọ-ọwọ́ náà tó bá pàpà ní àkóràn àrùn náà lọ́wọ́ níní àìsàn náà lẹ́ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.[3] À ń fún ni ní àjẹsára náà nípasẹ̀ abẹ́rẹ́ tí a ń gún sínú awọ ara ẹni.[1] Kò sí ẹ̀rí tó fihanni pé ènìyàn nílò àfikún ìwọ̀n àjẹsára náà lẹ́yìn èyítí a bá ti kọ́kọ́ fún ni.[1] A tún lè lò ó láti fi ṣe ìtọ́jú àwọn oríṣi àrùn jejere àpò-ìtọ̀ kan.[4]
Àtúnbọ̀tán kíkankíkan kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ojú ibi abẹ́rẹ́ náà a má a pupa yòò, a má a wú, a sì má a dun ni. Ọgbẹ́-inú kékeré kán náà lè wáyé, pẹ̀lú àpá díẹ̀ lẹ́yìn tí ojú ibi abẹ́rẹ́ náà bá jiná. Àtúnbọ̀tán wọ́pọ̀ púpọ̀ lára àwọn ènìyàn tí agbára àti kojú àìsàn wọn kò bá múnádóko, a sì má a lágbára púpọ̀. Ó léwú láti lò ó nígbàtí ènìyàn bá lóyún. A ṣe àgbéjáde àjẹsára náà láti ara kòkòrò àìlèfojúrí kan tí à ń pè ní Mycobacterium bovis èyítí a má a ń sábà rí lára àwọn mààlúù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ kòkòrò náà di aláìlágbára, ó ṣì wà láàyè.[1]
A lo àjẹsára BCG fún ìwòsàn fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1921.[1] Ó wà lórí Àkójọ Àwọn Egbògi Kòṣeémáàní ti Àjọ Ìlera Àgbáyé (World Health Organization's List of Essential Medicines), àwọn òògùn tó ṣe pàtàkì jùlọ tí a nílò fún ètò ìlera ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ yòówù.[5] Iye owó rẹ̀ lójú pálí jẹ́ 0.16 USD fún ìwọ̀n egbògi náà kanṣoṣo ní ọdún 2014.[6] Ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà iye owó rẹ̀ jẹ́ 100 sí 200 USD.[7] Lọ́dọọdún a má a ń fún iye àwọn ọmọ-ọwọ́ tó tó 100 mílíọ̀nù ní àjẹsára náà.[1]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 1.2 1.3 1.4 1.5 1.6 1.7 1.8 "BCG Vaccine: WHO position paper" (PDF).
- ↑ "Revised BCG vaccination guidelines for infants at risk for HIV infection."
- ↑ Roy, A; Eisenhut, M; Harris, RJ; Rodrigues, LC; Sridhar, S; Habermann, S; Snell, L; Mangtani, P; Adetifa, I; Lalvani, A; Abubakar, I (5 August 2014).
- ↑ Houghton, BB; Chalasani, V; Hayne, D; Grimison, P; Brown, CS; Patel, MI; Davis, ID; Stockler, MR (May 2013).
- ↑ "WHO Model List of EssentialMedicines" (PDF).
- ↑ "Vaccine, Bcg"[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́].
- ↑ Hamilton, Richart (2015).