Jump to content

Abrahamu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Abraham)
Abrahamu
An angel prevents the sacrifice of Isaac.
Abraham and Isaac by Rembrandt
Ọjọ́ìbíTheological figure - traditionally 2000 BCE
Ur Kaśdim or Haran
AláìsíTheological figure - traditionally 1825 BCE
Machpelah,[1] Canaan
Àwọn ọmọIshmael
Isaac
Zimran
Jokshan
Medan
Midian
Ishbak
Shuah
Parent(s)Terach

Abrahamu (Hébérù: אַבְרָהָם, Modern Avraham Tiberian ʾAḇrāhām, Lárúbáwá: إبراهيم‎, Ibrāhīm, ʾAbrəham) ni eni tí ó dá ilẹ̀ àwon Júù sílè. Wọ́n bí i ní Ur. Ọmọ Terah ni Abram. Ó sí ló sí Haran ní gusu Mesopotama pẹ̀lú bàbá rẹ̀, Ìyàwó rẹ̀ Sarah àti Lot tó jẹ́ ‘nephew’ rẹ̀ Nígbà tí ó lọ sí Kénáànì, ó gbọ́ ìpè Jehovah pé ibẹ̀ ni ilẹ̀ ìlérí fún àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó gba ìlérí Ọlọ́run yìí. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti gbé Egypt ní àsìkò ìyàn tí òun àti Lọ́ọ̀tì sì ti pínyà ní Bethon, ó lọ dó sí Hebrian. Nígbà tí Jehovah yí orúkọ rẹ̀ sí Abraham èyí tí i ṣe baba orílẹ̀ èdè púpọ̀, Jehovah ṣe ìlérí fún un pé òun yóò fún ní ọmọ tí yóò jogún rẹ̀. Jehovah dán an wò pé kí ó pa Isaac ọmọ rẹ̀ fún ìrúbọ. Bí ó ti fẹ́ẹ́ ṣe é ni Jehovah fi ọ̀dọ́ àgùntan kan rọ́pò ọmọ yìí. Láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ̀ Ikejì, Keturah, ó bí ọmọkùnrin mẹ́fà. Wọ́n sin ín síu iho (cave) Machpelah.