Kòkó
Èso Kòkó tàbí Kòkó ( /ˈkəʊ.kəʊ/), ni wọ́n tún ń dà pè ní ẹ̀wà kòkó ( /kəˈkaʊ/),[1] ni ohun ọ̀gbìn kan tí ó so sí ara igi tí ìrísí rẹ̀ fẹ́ fara pẹ́ èso Igi Obì. Orúkọ èso yí wá láti inú èdè Spain tí wọ́n pé ní: "cacao", tí àwọn náà mú orúkọ yí láti inú ọ̀rọ̀ "Nahuatl". Ọ̀rọ̀ "cacahautil" yí wọ́n tún ṣe àgbélẹ̀rọ rẹ̀ láti inú gbólóhùn "Mije-Sokean" tí ìpìlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ kakawa.
Ìtàn rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Igi tàbí èso Kòkó ni ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn Amazon Basin. Àwọn ènìyàn Olmecs àti Mokaya rí wọ́n jẹ́ (Mexico and Central America). Ní n kan bí ẹgbẹ̀rin ọdún (4,000 years) sẹ́yìn, ni wọ́n ti ń jẹ tàbí mu tí wọ́n si ń fi pèsè ohun jíjẹ aládìídùn láàrín àwọn Yutacan pàá pàá jùlọ àwọn Maya.
Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ń pèsè Kòkó
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Pípèsè Kòkó – 2017 | |
---|---|
Àwọn Orílẹ̀-èdè | (tonnes) |
Ní ọdún 2017, iye kòkó tí wọ́n pẹ̀sè láapapọ̀ jẹ́ 5.2 million tonnes, tí orílẹ̀-èdè Ivory Coast léwájú pẹ̀lú ìdá 38%. Àwọn mìíràn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tún pèsè kòkó tún ni: Ghana (17%) àti Indonesia (13%).
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Cacao". Free Dictionary. Retrieved 17 February 2015.
- ↑ "Cocoa bean production in 2017, Crops/Regions/World list/Production Quantity (pick lists)". UN Food and Agriculture Organization, Corporate Statistical Database (FAOSTAT). 2018. Retrieved 28 March 2019.