Jump to content

Moji Akinfenwa

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mojísólúwa O Akínfẹ́nwá
Senator for Osun East
In office
May 1999 – May 2003
Arọ́pòIyìọlá Omíṣore
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí1930
Iléṣà, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ,Nigerian Protectorate
AláìsíOctober 10, 2019(2019-10-10) (ọmọ ọdún 88–89)
Ibadan, Oyo State, Nigeria

[1][2] Moji Akinfenwa (1930-2019) jẹ́ olóṣèlú àti ọmọ Ilé Aṣòfin Àgbà Naijiria nígbà kan rí láti ọdún 1999 sí ọdún 2003 tí ó ṣojú Ìlà Oòrùn Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy (AD). Wọ́n yàn án sínu ìgbìmọ̀ tí ó ń ṣe àṣàyàn.

Ìgbésí ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní oṣù Kejìlá ọdún 2003, Alhaji Ahmed Abdulkadir, tí ó jẹ́ Alága gboggbògbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy tí ó ń fipò silẹ̀ kọ̀wé sí Àjọ Elétò Ìdìbò (INEC), láti fi ẹsẹ̀ Akínfẹ́nwá rinlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alága gbogbo gbò tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú náà náà. Ẹgbẹ́ òṣèlú yí ti pín tẹ́lẹ́ sí ọ̀nà méjì , tí Olóyè Bísí Àkàndésì jẹ́ adarí fún apá kejì. Fúndí èyí, nínú oṣù kejì ọdún 2004, àjọ INEC pe ìpàdé àwọn olórí olórí nínú ẹgbẹ́ náà yàtọ̀ sí àwọn adarí méjèjì yí, láti bá wọn paná aáwọ̀ tó wà nínú ẹgbẹ́ náà àmọ́ tí ìpẹ̀tù sááwọ̀ náà sì forí ṣánpọ́n. Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re sì fi ifeẹ́ wọn hàn sí Akínfẹnwa láti di Alága gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ náà. Akínfẹnwá fẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀ẹ̀ ní oṣù Kejì ọdún 2006 wípé òun ni Alága gbogbo gbò fún ẹgbẹ́ òṣèlú Alliance for Democracy ní ilẹ̀ Nàìjíríà, wípé kìí ṣe Olóyè Bísí Àkàndé.



  1. "FEDERAL REPUBLIC OF NIGERIA LEGISLATIVE ELECTION OF 20 FEBRUARY AND 7 MARCH 1999". Psephos. Retrieved 2010-06-24. 
  2. "Congressional Committees". Nigeria Congress. Archived from the original on 2009-11-18. Retrieved 2010-06-24.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)